Native Bible

Numbers 3:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tábìlì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

Numbers 3:31 in English

Numbers 3:31 · Berean Standard Bible

Their duties were the ark, the table, the lampstand, the altars, the articles of the sanctuary used with them, and the curtain—all the service for these items.

Context

29Àwọn ìdílé Kohati yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúsù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́. 30Olórí àwọn ìdílé Kohati ni Elisafani ọmọ Usieli. 31Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tábìlì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn. 32Eleasari ọmọ Aaroni àlùfáà ni alákòóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Lefi. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́. 33Ti Merari ni ìran Mahili àti Muṣi, àwọn ni ìran Merari.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.