Numeri 24:8
Numbers 24:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá; wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré. Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run, wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú; wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.
Numbers 24:8 in English
Numbers 24:8 · Berean Standard Bible
God brought him out of Egypt with strength like a wild ox, to devour hostile nations and crush their bones, to pierce them with arrows.
Context
6“Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde,
gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá,
gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn,
gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò. 7Omi yóò sàn láti inú garawa:
èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
“Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ;
ìjọba wọn yóò di gbígbéga. 8“Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá;
wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré.
Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run,
wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú;
wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ. 9Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún,
bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn?
“Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ,
kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!” 10Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.