Numeri 24:10
Numbers 24:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.
Numbers 24:10 in English
Numbers 24:10 · Berean Standard Bible
Then Balak’s anger burned against Balaam, and he struck his hands together and said to Balaam, “I summoned you to curse my enemies, but behold, you have persisted in blessing them these three times.
Context
8“Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá;
wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré.
Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run,
wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú;
wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ. 9Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún,
bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn?
“Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ,
kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!” 10Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí. 11Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.” 12Balaamu dá Balaki lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.