Numeri 24:6
Numbers 24:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde, gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá, gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn, gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.
Numbers 24:6 in English
Numbers 24:6 · Berean Standard Bible
They spread out like palm groves,* like gardens beside a stream, like aloes the LORD has planted, like cedars beside the waters.
Context
4àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,
ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ là kedere. 5“Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu,
àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli! 6“Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde,
gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá,
gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn,
gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò. 7Omi yóò sàn láti inú garawa:
èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
“Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ;
ìjọba wọn yóò di gbígbéga. 8“Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá;
wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré.
Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run,
wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú;
wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.