Numeri 24:4
Numbers 24:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ là kedere.
Numbers 24:4 in English
Numbers 24:4 · Berean Standard Bible
the prophecy of one who hears the words of God, who sees a vision from the Almighty,* who bows down with eyes wide open:
Context
2Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀ 3ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀,
“Àsọtẹ́lẹ̀ tí Balaamu ọmọ Beori,
àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere, 4àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,
ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ là kedere. 5“Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu,
àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli! 6“Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde,
gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá,
gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn,
gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.