Native Bible

Numbers 24:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀

Numbers 24:2 in English

Numbers 24:2 · Berean Standard Bible

When Balaam looked up and saw Israel encamped tribe by tribe, the Spirit of God came upon him,

Context

1Nísinsin yìí nígbà tí Balaamu rí i wí pé ó tẹ́ Olúwa lọ́rùn láti bùkún àwọn Israẹli, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá aginjù. 2Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀ 3ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, “Àsọtẹ́lẹ̀ tí Balaamu ọmọ Beori, àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere, 4àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ là kedere.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.