Numeri 24:15
Numbers 24:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe: “Òwe Balaamu ọmọ Beori, òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere,
Numbers 24:15 in English
Numbers 24:15 · Berean Standard Bible
Then Balaam lifted up an oracle, saying, “This is the prophecy of Balaam son of Beor, the prophecy of a man whose eyes are open,
Context
13‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’? 14Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.” 15Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe:
“Òwe Balaamu ọmọ Beori,
òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere, 16ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wí,
tí ó sì mọ ìmọ̀ Ọ̀gá-ògo,
tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,
ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ṣí: 17“Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí.
Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́.
Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jakọbu;
yóò yọ jáde láti Israẹli.
Yóò tẹ̀ fọ́ orí Moabu,
yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Seti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.