Native Bible

Numbers 24:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’?

Numbers 24:13 in English

Numbers 24:13 · Berean Standard Bible

that even if Balak were to give me his house full of silver and gold, I could not do anything of my own accord, good or bad, to go beyond the command of the LORD? I will speak whatever the LORD says.

Context

11Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.” 12Balaamu dá Balaki lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé, 13‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’? 14Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.” 15Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe: “Òwe Balaamu ọmọ Beori, òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.