Native Bible

Numbers 24:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”

Numbers 24:14 in English

Numbers 24:14 · Berean Standard Bible

Now I am going back to my people, but come, let me warn you what this people will do to your people in the days to come.”

Context

12Balaamu dá Balaki lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé, 13‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’? 14Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.” 15Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe: “Òwe Balaamu ọmọ Beori, òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere, 16ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wí, tí ó sì mọ ìmọ̀ Ọ̀gá-ògo, tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ṣí:

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.