Native Bible

Numbers 24:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí. Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́. Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jakọbu; yóò yọ jáde láti Israẹli. Yóò tẹ̀ fọ́ orí Moabu, yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Seti.

Numbers 24:17 in English

Numbers 24:17 · Berean Standard Bible

I see him, but not now; I behold him, but not near. A star will come forth from Jacob, and a scepter will arise from Israel. He will crush the skulls * of Moab and strike down all the sons of Sheth.

Context

15Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe: “Òwe Balaamu ọmọ Beori, òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere, 16ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wí, tí ó sì mọ ìmọ̀ Ọ̀gá-ògo, tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ṣí: 17“Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí. Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́. Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jakọbu; yóò yọ jáde láti Israẹli. Yóò tẹ̀ fọ́ orí Moabu, yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Seti. 18Wọn yóò borí Edomu; yóò ṣẹ́gun Seiri ọ̀tá rẹ̀, ṣùgbọ́n Israẹli yóò dàgbà nínú agbára. 19Olórí yóò jáde láti Jakọbu yóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.