Numeri 21:26
Numbers 21:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni.
Numbers 21:26 in English
Numbers 21:26 · Berean Standard Bible
Heshbon was the city of Sihon king of the Amorites, who had fought against the former king of Moab and taken all his land as far as the Arnon.
Context
24Àmọ́, Israẹli ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Arnoni lọ dé Jabbok, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi. 25Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká. 26Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni. 27Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé,
“Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;
jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò. 28“Iná jáde láti Heṣboni,
ọ̀wọ́-iná láti Sihoni.
Ó jó Ari àti Moabu run,
àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.