Numeri 21:27
Numbers 21:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé, “Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́; jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò.
Numbers 21:27 in English
Numbers 21:27 · Berean Standard Bible
That is why the poets say: “Come to Heshbon, let it be rebuilt; let the city of Sihon be restored.
Context
25Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká. 26Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni. 27Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé,
“Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;
jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò. 28“Iná jáde láti Heṣboni,
ọ̀wọ́-iná láti Sihoni.
Ó jó Ari àti Moabu run,
àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni. 29Ègbé ní fún ọ, ìwọ Moabu!
Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kemoṣi!
Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá
àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn
fún Sihoni ọba àwọn Amori.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.