Native Bible

Numbers 21:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká.

Numbers 21:25 in English

Numbers 21:25 · Berean Standard Bible

Israel captured all the cities of the Amorites and occupied them, including Heshbon and all its villages.

Context

23Ṣùgbọ́n Sihoni kò ní jẹ́ kí àwọn Israẹli kọjá ní ilẹ̀ wọn. Ó pe àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì wọ́de ogun lọ sí aginjù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ó dé Jahasi, ó bá àwọn ọmọ Israẹli jà. 24Àmọ́, Israẹli ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Arnoni lọ dé Jabbok, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi. 25Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká. 26Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni. 27Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé, “Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́; jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.