Numeri 21:28
Numbers 21:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Iná jáde láti Heṣboni, ọ̀wọ́-iná láti Sihoni. Ó jó Ari àti Moabu run, àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni.
Numbers 21:28 in English
Numbers 21:28 · Berean Standard Bible
For a fire went out from Heshbon, a blaze from the city of Sihon. It consumed Ar of Moab, the rulers of Arnon’s heights.
Context
26Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni. 27Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé,
“Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;
jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò. 28“Iná jáde láti Heṣboni,
ọ̀wọ́-iná láti Sihoni.
Ó jó Ari àti Moabu run,
àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni. 29Ègbé ní fún ọ, ìwọ Moabu!
Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kemoṣi!
Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá
àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn
fún Sihoni ọba àwọn Amori. 30“Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú;
a ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni.
A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa,
tí ó sì fi dé Medeba.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.