Numeri 21:30
Numbers 21:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú; a ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni. A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa, tí ó sì fi dé Medeba.”
Numbers 21:30 in English
Numbers 21:30 · Berean Standard Bible
But we have overthrown them; Heshbon is destroyed as far as Dibon. We demolished them as far as Nophah, which reaches to Medeba.*”
Context
28“Iná jáde láti Heṣboni,
ọ̀wọ́-iná láti Sihoni.
Ó jó Ari àti Moabu run,
àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni. 29Ègbé ní fún ọ, ìwọ Moabu!
Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kemoṣi!
Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá
àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn
fún Sihoni ọba àwọn Amori. 30“Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú;
a ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni.
A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa,
tí ó sì fi dé Medeba.” 31Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli sì ń gbé ní ilẹ̀ Amori. 32Lẹ́yìn ìgbà tí Mose rán ayọ́lẹ̀wò lọ sí Jaseri, àwọn ọmọ Israẹli sì gba àwọn agbègbè tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Amori tó wà níbẹ̀ jáde.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.