Numeri 21:31
Numbers 21:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli sì ń gbé ní ilẹ̀ Amori.
Numbers 21:31 in English
Numbers 21:31 · Berean Standard Bible
So Israel lived in the land of the Amorites.
Context
29Ègbé ní fún ọ, ìwọ Moabu!
Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kemoṣi!
Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá
àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn
fún Sihoni ọba àwọn Amori. 30“Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú;
a ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni.
A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa,
tí ó sì fi dé Medeba.” 31Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli sì ń gbé ní ilẹ̀ Amori. 32Lẹ́yìn ìgbà tí Mose rán ayọ́lẹ̀wò lọ sí Jaseri, àwọn ọmọ Israẹli sì gba àwọn agbègbè tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Amori tó wà níbẹ̀ jáde. 33Nígbà náà wọ́n pẹ̀yìndà wọ́n sì gòkè lọ sí Baṣani, Ogu ọba ti Baṣani àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wọ́de ogun jáde láti pàdé wọn ní ojú ogun ní Edrei.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.