Nahumu 3:14
Nahum 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Pọn omi nítorí ìhámọ́, mú ilé ìṣọ́ rẹ lágbára sí i wọ inú amọ̀ kí o sì tẹ erùpẹ̀, kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le.
Nahum 3:14 in English
Nahum 3:14 · Berean Standard Bible
Draw your water for the siege; strengthen your fortresses. Work the clay and tread the mortar; repair the brick kiln!
Context
12Gbogbo ilé ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́
pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn;
nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n,
ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun. 13Kíyèsi gbogbo àwọn jagunjagun!
Obìnrin ni gbogbo wọn.
Ojú ibodè rẹ ní a ó ṣí sílẹ̀ gbagada,
fún àwọn ọ̀tá rẹ;
iná yóò jó ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ibodè rẹ. 14Pọn omi nítorí ìhámọ́,
mú ilé ìṣọ́ rẹ lágbára sí i
wọ inú amọ̀
kí o sì tẹ erùpẹ̀,
kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le. 15Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run;
idà yóò sì ké ọ kúrò,
yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò,
yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata,
àní, di púpọ̀ bí eṣú! 16Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀
títí wọn yóò fi pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ,
ṣùgbọ́n bi eṣú ni wọn yóò sọ ilẹ̀ náà di ahoro, wọn yóò sì fò lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.