Nahumu 3:13
Nahum 3:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kíyèsi gbogbo àwọn jagunjagun! Obìnrin ni gbogbo wọn. Ojú ibodè rẹ ní a ó ṣí sílẹ̀ gbagada, fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná yóò jó ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ibodè rẹ.
Nahum 3:13 in English
Nahum 3:13 · Berean Standard Bible
Look at your troops— they are like your women! The gates of your land are wide open to your enemies; fire consumes their bars.
Context
11Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara;
a ó sì fi ọ́ pamọ́
ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà. 12Gbogbo ilé ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́
pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn;
nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n,
ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun. 13Kíyèsi gbogbo àwọn jagunjagun!
Obìnrin ni gbogbo wọn.
Ojú ibodè rẹ ní a ó ṣí sílẹ̀ gbagada,
fún àwọn ọ̀tá rẹ;
iná yóò jó ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ibodè rẹ. 14Pọn omi nítorí ìhámọ́,
mú ilé ìṣọ́ rẹ lágbára sí i
wọ inú amọ̀
kí o sì tẹ erùpẹ̀,
kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le. 15Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run;
idà yóò sì ké ọ kúrò,
yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò,
yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata,
àní, di púpọ̀ bí eṣú!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.