Nahumu 3:11
Nahum 3:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara; a ó sì fi ọ́ pamọ́ ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà.
Nahum 3:11 in English
Nahum 3:11 · Berean Standard Bible
You too will become drunk; you will go into hiding and seek refuge from the enemy.
Context
9Etiopia àti Ejibiti ni agbára rẹ, kò sí ní òpin;
Puti àti Libia ni àwọn olùgbèjà rẹ̀. 10Síbẹ̀síbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn
o sì lọ sí oko ẹrú.
Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀
ní orí ìta gbogbo ìgboro.
Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin,
gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè. 11Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara;
a ó sì fi ọ́ pamọ́
ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà. 12Gbogbo ilé ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́
pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn;
nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n,
ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun. 13Kíyèsi gbogbo àwọn jagunjagun!
Obìnrin ni gbogbo wọn.
Ojú ibodè rẹ ní a ó ṣí sílẹ̀ gbagada,
fún àwọn ọ̀tá rẹ;
iná yóò jó ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ibodè rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.