Nahumu 3:16
Nahum 3:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀ títí wọn yóò fi pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ, ṣùgbọ́n bi eṣú ni wọn yóò sọ ilẹ̀ náà di ahoro, wọn yóò sì fò lọ.
Nahum 3:16 in English
Nahum 3:16 · Berean Standard Bible
You have multiplied your merchants more than the stars of the sky. The young locust strips the land and flies away.
Context
14Pọn omi nítorí ìhámọ́,
mú ilé ìṣọ́ rẹ lágbára sí i
wọ inú amọ̀
kí o sì tẹ erùpẹ̀,
kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le. 15Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run;
idà yóò sì ké ọ kúrò,
yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò,
yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata,
àní, di púpọ̀ bí eṣú! 16Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀
títí wọn yóò fi pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ,
ṣùgbọ́n bi eṣú ni wọn yóò sọ ilẹ̀ náà di ahoro, wọn yóò sì fò lọ. 17Àwọn aládé rẹ̀ dàbí eṣú,
àwọn ọ̀gágun rẹ dàbí ẹlẹ́ǹgà ńlá,
èyí tí ń dó sínú ọgbà ni ọjọ́ òtútù,
ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn jáde, wọ́n sálọ,
ẹnìkan kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé wà. 18Ìwọ ọba Asiria,
àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ ń tòògbé;
àwọn ọlọ́lá rẹ dùbúlẹ̀ láti sinmi.
Àwọn ènìyàn rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè ńlá,
tí ẹnikẹ́ni kò sì kó wọn jọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.