Mika 7:14
Micah 7:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ, èyí tí ó ń dágbé nínú igbó ní àárín Karmeli. Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi bí ọjọ́ ìgbàanì.
Micah 7:14 in English
Micah 7:14 · Berean Standard Bible
Shepherd with Your staff Your people, the flock of Your inheritance. They live alone in a woodland, surrounded by pastures.* Let them graze in Bashan and Gilead, as in the days of old.
Context
12Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ
láti Asiria àti ìlú ńlá Ejibiti
àní láti Ejibiti dé Eufurate
láti Òkun dé Òkun
àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá. 13Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé inú rẹ̀,
nítorí èso ìwà wọn. 14Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ,
èyí tí ó ń dágbé nínú igbó
ní àárín Karmeli.
Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi
bí ọjọ́ ìgbàanì. 15“Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Ejibiti wá,
ni èmi yóò fi ohun ìyanu hàn án.” 16Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n,
nínú gbogbo agbára wọn.
Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn,
etí wọn yóò sì di.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.