Native Bible

Micah 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ láti Asiria àti ìlú ńlá Ejibiti àní láti Ejibiti dé Eufurate láti Òkun dé Òkun àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.

Micah 7:12 in English

Micah 7:12 · Berean Standard Bible

On that day they will come to you from Assyria and the cities of Egypt, even from Egypt to the Euphrates,* from sea to sea and mountain to mountain.

Context

10Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé, “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?” Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀; nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ òpópó. 11Ọjọ́ tí a ó mọ odi rẹ yóò dé, ọjọ́ náà ni àṣẹ yóò jìnnà réré. 12Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ láti Asiria àti ìlú ńlá Ejibiti àní láti Ejibiti dé Eufurate láti Òkun dé Òkun àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá. 13Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé inú rẹ̀, nítorí èso ìwà wọn. 14Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ, èyí tí ó ń dágbé nínú igbó ní àárín Karmeli. Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi bí ọjọ́ ìgbàanì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.