Native Bible

Micah 7:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé, “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?” Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀; nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ òpópó.

Micah 7:10 in English

Micah 7:10 · Berean Standard Bible

Then my enemy will see and will be covered with shame— she who said to me, “Where is the LORD your God?” My eyes will see her; at that time she will be trampled like mud in the streets.

Context

8Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi. Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde. Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi. 9Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i, èmi yóò faradà ìbínú Olúwa, títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò, tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi. Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀; èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀. 10Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé, “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?” Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀; nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ òpópó. 11Ọjọ́ tí a ó mọ odi rẹ yóò dé, ọjọ́ náà ni àṣẹ yóò jìnnà réré. 12Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ láti Asiria àti ìlú ńlá Ejibiti àní láti Ejibiti dé Eufurate láti Òkun dé Òkun àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.