Native Bible

Micah 7:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i, èmi yóò faradà ìbínú Olúwa, títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò, tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi. Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀; èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀.

Micah 7:9 in English

Micah 7:9 · Berean Standard Bible

Because I have sinned against Him, I must endure the rage of the LORD, until He argues my case and executes justice for me. He will bring me into the light; I will see His righteousness.

Context

7Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa, èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi. 8Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi. Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde. Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi. 9Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i, èmi yóò faradà ìbínú Olúwa, títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò, tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi. Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀; èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀. 10Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé, “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?” Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀; nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ òpópó. 11Ọjọ́ tí a ó mọ odi rẹ yóò dé, ọjọ́ náà ni àṣẹ yóò jìnnà réré.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.