Native Bible

Micah 7:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi. Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde. Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi.

Micah 7:8 in English

Micah 7:8 · Berean Standard Bible

Do not gloat over me, my enemy! Though I have fallen, I will arise; though I sit in darkness, the LORD will be my light.

Context

6Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀, aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀, ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀. 7Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa, èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi. 8Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi. Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde. Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi. 9Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i, èmi yóò faradà ìbínú Olúwa, títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò, tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi. Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀; èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀. 10Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé, “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?” Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀; nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ òpópó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.