Mika 7:15
Micah 7:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Ejibiti wá, ni èmi yóò fi ohun ìyanu hàn án.”
Micah 7:15 in English
Micah 7:15 · Berean Standard Bible
As in the days when you came out of Egypt, I will show My wonders.
Context
13Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé inú rẹ̀,
nítorí èso ìwà wọn. 14Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ,
èyí tí ó ń dágbé nínú igbó
ní àárín Karmeli.
Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi
bí ọjọ́ ìgbàanì. 15“Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Ejibiti wá,
ni èmi yóò fi ohun ìyanu hàn án.” 16Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n,
nínú gbogbo agbára wọn.
Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn,
etí wọn yóò sì di. 17Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò,
wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló.
Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,
wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.