Native Bible

Lamentations 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé gbogbo ìní rẹ; o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ— àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀ láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.

Lamentations 1:10 in English

Lamentations 1:10 · Berean Standard Bible

The adversary has seized all her treasures. For she has seen the nations enter her sanctuary— those You had forbidden to enter Your assembly.

Context

8Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ ó sì ti di aláìmọ́. Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀; ó kérora fúnra rẹ̀, ó sì lọ kúrò. 9Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀. Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu; olùtùnú kò sì ṣí fún un. “Wo ìpọ́njú mi, Olúwa, nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.” 10Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé gbogbo ìní rẹ; o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ— àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀ láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ. 11Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ; wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ láti mú wọn wà láààyè. “Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó, nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.” 12“Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín? Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá. Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà tí a fi fún mi, ti Olúwa mú wá fún mi ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.