Ẹkún Jeremiah 1:11
Lamentations 1:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ; wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ láti mú wọn wà láààyè. “Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó, nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”
Lamentations 1:11 in English
Lamentations 1:11 · Berean Standard Bible
All her people groan as they search for bread. They have traded their treasures for food to keep themselves alive. Look, O LORD, and consider, for I have become despised.
Context
9Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀.
Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu;
olùtùnú kò sì ṣí fún un.
“Wo ìpọ́njú mi, Olúwa,
nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.” 10Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé
gbogbo ìní rẹ;
o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè
tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ—
àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀
láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ. 11Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora
bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;
wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ
láti mú wọn wà láààyè.
“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó,
nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.” 12“Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín?
Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá.
Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà
tí a fi fún mi, ti
Olúwa mú wá fún mi
ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀. 13“Ó rán iná láti òkè
sọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi.
Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi,
ó sì yí mi padà.
Ó ti pa mí lára
mó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.