Native Bible

Lamentations 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ ó sì ti di aláìmọ́. Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀; ó kérora fúnra rẹ̀, ó sì lọ kúrò.

Lamentations 1:8 in English

Lamentations 1:8 · Berean Standard Bible

Jerusalem has sinned greatly; therefore she has become an object of scorn. All who honored her now despise her, for they have seen her nakedness;* she herself groans and turns away.

Context

6Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé kúrò lọ́dọ̀ ọmọbìnrin Sioni. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dàbí i àgbọ̀nrín tí kò rí ewé tútù jẹ; nínú àárẹ̀ wọ́n sáré níwájú ẹni tí ó ń lé wọn. 7Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni Jerusalẹmu rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀ tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́. Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, kò sì ṣí olùrànlọ́wọ́ fún un. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà. 8Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ ó sì ti di aláìmọ́. Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀; ó kérora fúnra rẹ̀, ó sì lọ kúrò. 9Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀. Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu; olùtùnú kò sì ṣí fún un. “Wo ìpọ́njú mi, Olúwa, nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.” 10Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé gbogbo ìní rẹ; o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ— àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀ láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.