Native Bible

Job 8:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀.

Job 8:12 in English

Job 8:12 · Berean Standard Bible

While the shoots are still uncut, they dry up quicker than grass.

Context

10Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ? Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá? 11Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀ tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi? 12Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀. 13Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo. 14Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.