Native Bible

Job 8:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ? Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?

Job 8:10 in English

Job 8:10 · Berean Standard Bible

Will they not teach you and tell you, and speak from their understanding?

Context

8“Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn. 9Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan, nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé. 10Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ? Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá? 11Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀ tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi? 12Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.