Native Bible

Job 8:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.

Job 8:14 in English

Job 8:14 · Berean Standard Bible

His confidence is fragile; his security is in a spider’s web.

Context

12Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀. 13Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo. 14Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn. 15Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró, yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́. 16Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn, ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.