Native Bible

Job 34:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú, níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí.

Job 34:22 in English

Job 34:22 · Berean Standard Bible

There is no darkness or deep shadow where the workers of iniquity can hide.

Context

20Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú, àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ; a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀. 21“Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo. 22Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú, níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí. 23Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan, kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run. 24Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí, a sì fi ẹlòmíràn dípò wọn,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.