Jobu 34:20
Job 34:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú, àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ; a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.
Job 34:20 in English
Job 34:20 · Berean Standard Bible
They die in an instant, in the middle of the night. The people convulse and pass away; the mighty are removed without human hand.
Context
18O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘Ènìyàn búburú ní ìwọ,’
tàbí fún àwọn ọmọ-aládé pé, ‘Ìkà ni ẹ̀yin,’ 19mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé
tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ,
nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe? 20Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú,
àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ;
a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀. 21“Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn,
òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo. 22Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú,
níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.