Jobu 34:21
Job 34:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.
Job 34:21 in English
Job 34:21 · Berean Standard Bible
For His eyes are on the ways of a man, and He sees his every step.
Context
19mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé
tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ,
nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe? 20Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú,
àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ;
a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀. 21“Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn,
òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo. 22Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú,
níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí. 23Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan,
kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.