Native Bible

Job 12:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀.

Job 12:5 in English

Job 12:5 · Berean Standard Bible

The one at ease scorns misfortune as the fate of those whose feet are slipping.

Context

3Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin; èmi kò kéré sí i yín. Àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí? 4“Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn, à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà! 5Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀. 6Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù; àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu, àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn. 7“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.