Native Bible

Job 12:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.

Job 12:7 in English

Job 12:7 · Berean Standard Bible

But ask the animals, and they will instruct you; ask the birds of the air, and they will tell you.

Context

5Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀. 6Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù; àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu, àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn. 7“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ. 8Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú òkun yóò sì sọ fún ọ. 9Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí pé, ọwọ́ Olúwa ni ó ṣe nǹkan yìí?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.