Jobu 12:6
Job 12:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù; àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu, àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.
Job 12:6 in English
Job 12:6 · Berean Standard Bible
The tents of robbers are safe, and those who provoke God are secure— those who carry their god in their hands.*
Context
4“Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,
tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn,
à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà! 5Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà
gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀. 6Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù;
àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu,
àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn. 7“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́,
àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ. 8Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ,
àwọn ẹja inú òkun yóò sì sọ fún ọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.