Jobu 12:3
Job 12:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin; èmi kò kéré sí i yín. Àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?
Job 12:3 in English
Job 12:3 · Berean Standard Bible
But I also have a mind; I am not inferior to you. Who does not know such things as these?
Context
1Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé, 2“Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà,
ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín! 3Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin;
èmi kò kéré sí i yín.
Àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí? 4“Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,
tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn,
à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà! 5Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà
gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.