Jeremiah 9:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè àti ẹkún ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì. Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn. Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sálọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.
Jeremiah 9:10 in English
Jeremiah 9:10 · Berean Standard Bible
I will take up a weeping and wailing for the mountains, a dirge over the wilderness pasture, for they have been scorched so no one passes through, and the lowing of cattle is not heard. Both the birds of the air and the beasts have fled; they have gone away.
Context
8Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró;
ó ń sọ ẹ̀tàn.
Oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀,
ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀. 9Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”
ni Olúwa wí.
“Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara
mi lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?” 10Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè
àti ẹkún ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì.
Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀.
A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn.
Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sálọ,
bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ. 11“Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtì
àlàpà àti ihò àwọn ìkookò.
Èmi ó sì sọ ìlú Juda di ahoro
tí ẹnikẹ́ni kò sì ní le è gbé.” 12Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.