Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?

Jeremiah 9:12 in English

Jeremiah 9:12 · Berean Standard Bible

Who is the man wise enough to understand this? To whom has the mouth of the LORD spoken, that he may explain it? Why is the land destroyed and scorched like a desert, so no one can pass through it?

Context

10Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè àti ẹkún ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì. Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn. Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sálọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ. 11“Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtì àlàpà àti ihò àwọn ìkookò. Èmi ó sì sọ ìlú Juda di ahoro tí ẹnikẹ́ni kò sì ní le è gbé.” 12Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá? 13Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi. 14Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.