Jeremiah 9:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi.
Jeremiah 9:13 in English
Jeremiah 9:13 · Berean Standard Bible
And the LORD answered, “It is because they have forsaken My law, which I set before them; they have not walked in it or obeyed My voice.
Context
11“Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtì
àlàpà àti ihò àwọn ìkookò.
Èmi ó sì sọ ìlú Juda di ahoro
tí ẹnikẹ́ni kò sì ní le è gbé.” 12Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá? 13Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi. 14Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn. 15Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.