Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.

Jeremiah 9:15 in English

Jeremiah 9:15 · Berean Standard Bible

Therefore this is what the LORD of Hosts, the God of Israel, says: “Behold, I will feed this people wormwood and give them poisoned water to drink.

Context

13Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi. 14Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn. 15Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé. 16Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.” 17Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá; sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.