Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá; sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.

Jeremiah 9:17 in English

Jeremiah 9:17 · Berean Standard Bible

This is what the LORD of Hosts says: “Take note, and summon the wailing women; send for the most skillful among them.

Context

15Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé. 16Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.” 17Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá; sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn. 18Jẹ́ kí wọn wá kíákíá, kí wọn wá pohùnréré ẹkún lé wa lórí títí ojú wa yóò fi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa. 19A gbọ́ igbe ìpohùnréré ẹkún ní Sioni: ‘Àwa ti ṣègbé tó! A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.