Jeremiah 9:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jẹ́ kí wọn wá kíákíá, kí wọn wá pohùnréré ẹkún lé wa lórí títí ojú wa yóò fi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa.
Jeremiah 9:18 in English
Jeremiah 9:18 · Berean Standard Bible
Let them come quickly and take up a lament over us, that our eyes may overflow with tears, and our eyelids may gush with water.
Context
16Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.” 17Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:
“Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá;
sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn. 18Jẹ́ kí wọn wá kíákíá,
kí wọn wá pohùnréré ẹkún
lé wa lórí títí ojú wa yóò
fi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa. 19A gbọ́ igbe ìpohùnréré
ẹkún ní Sioni:
‘Àwa ti ṣègbé tó!
A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀,
nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ” 20Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa;
ṣí etí yín sí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.
Kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìpohùnréré ẹkún,
kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.