Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró; ó ń sọ ẹ̀tàn. Oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀, ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.

Jeremiah 9:8 in English

Jeremiah 9:8 · Berean Standard Bible

Their tongues are deadly arrows; they speak deception. With his mouth a man speaks peace to his neighbor, but in his heart he sets a trap for him.

Context

6Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn,” ni Olúwa wí. 7Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi? 8Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró; ó ń sọ ẹ̀tàn. Oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀, ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀. 9Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara mi lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?” 10Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè àti ẹkún ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì. Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn. Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sálọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.