Jeremiah 9:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn,” ni Olúwa wí.
Jeremiah 9:6 in English
Jeremiah 9:6 · Berean Standard Bible
You dwell * in the midst of deception; in their deceit they refuse to know Me,” declares the LORD.
Context
4“Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ;
má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ.
Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ,
oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́. 5Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni
tó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn
láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn
di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ 6Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn;
wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn,”
ni Olúwa wí. 7Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:
“Wò ó, èmi dán wọn wo;
nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe?
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi? 8Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró;
ó ń sọ ẹ̀tàn.
Oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀,
ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.