Jeremiah 6:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun! Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán! Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán, ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.
Jeremiah 6:4 in English
Jeremiah 6:4 · Berean Standard Bible
‘Prepare for battle against her; rise up, let us attack at noon. Woe to us, for the daylight is fading; the evening shadows grow long.
Context
2Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run,
tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́. 3Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n.
Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká,
olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.” 4“Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun!
Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán!
Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán,
ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i. 5Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́
kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.” 6Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀
kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká.
Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò,
nítorí pé ó kún fún ìninilára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.