Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n. Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká, olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”

Jeremiah 6:3 in English

Jeremiah 6:3 · Berean Standard Bible

Shepherds and their flocks will come against her; they will pitch their tents all around her, each tending his own portion:

Context

1“Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò! Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu. Ẹ fọn fèrè ní Tekoa! Kí ẹ gbé àmì sókè lórí Beti-Hakeremu! Nítorí àjálù farahàn láti àríwá, àní ìparun tí ó lágbára. 2Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run, tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́. 3Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n. Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká, olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.” 4“Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun! Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán! Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán, ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i. 5Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́ kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.