Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run, tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́.

Jeremiah 6:2 in English

Jeremiah 6:2 · Berean Standard Bible

Though she is beautiful and delicate, I will destroy the Daughter of Zion.*

Context

1“Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò! Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu. Ẹ fọn fèrè ní Tekoa! Kí ẹ gbé àmì sókè lórí Beti-Hakeremu! Nítorí àjálù farahàn láti àríwá, àní ìparun tí ó lágbára. 2Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run, tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́. 3Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n. Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká, olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.” 4“Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun! Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán! Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán, ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.